Yoruba

Awon Elesin Abalaye Ipinle Oyo Ti Gbosuba Fun, Gomina Oyetola Lori Igbese Kikede Isinmi Lenuse Lati Saami Ayajo Ojo Isese Nipinle Osun

Awon elesin abalaye nipinle Oyo ti gbosuba fun, Gomina Ipinle Osun Ogbeni Gboyega Oyetola lori igbese kikede isinmi lenuse lati samin ayajo ojo isese nipinle.

Ninu atejade eyi ti alaga egbe awon elesin abalaye teka ipinle Oyo Ogbeni Adefabi Fadiran ati akowe, omowe Fakayode Fatunde fisita nilu Ibadan, tokasi pe Gomina ti fi emi igboye han, nipa sise atileyin fun asa ati ise Yoruba.

Atejade naa wa kesi awon omo egbe nipinle Oyo lati sajoyo odun Isese laisi gbungbun kan, ki won si gbadura fun Alafia ile Yourba, Orileede Nigeria, Ipinle Oyo ati agbegbe lapapo.

Ayajo odun Isese todun 2021 ni won nse ni gbogbo agbaye logunjo osu kejo, odoodun.

Ololade Afonja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *