Tag: Ilé ìgbìmọ̀ asòfin

  • Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ńfẹ́kí àfikún débá owó fún ètò àbò nínú ìsúná

    Ìgbìmọ̀ tón rírí isẹ́ ológun, nílé ìgbímọ̀ asòfin sọpé owónáà tójẹ́ billiọnu mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n naira tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún àwọn isẹ́ àkànse nílesẹ́ ológun nílẹ̀ Nàijírìa, nínú àbá ìsúná fún tọdún 2021, ni wọ́n sọpé kòtó rárá.

    Alága ìgbìmọ̀ náà, Sẹnatọ Alli Ndume ló sọ̀rọ̀ yí lásìkò táwọn ọ̀gágun wá síwájú ilé, láti sọ̀rọ̀ gbe àbá ìsúná ọ̀hún.

    Sẹnatọr Ndume wá pè fún kí àfikún débá owó tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ilésẹ́ ológun nínú ètò ìsúná, tó sì tọ́kasi bétò àbò se mẹ́hẹ láwọn apá ibìkan lórílẹ̀èdè yí.

    Ó fikun pé, ilésẹ́ ológun lón sisẹ́ nípinlẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nílẹ̀ yí, tíwọ́n sì nílò owó tótó láti lè sisẹ́ wọn bótitọ́ àti bótiyẹ papa lórí ríra àwọn on èlò ìjagun.

    Jibikẹ/Afọnja

  • Ilé ìgbìmọ̀ asòfin jẹ́jẹ láti fọwọ́ òfin mú àwọn ilésẹ́ tokọ̀ láti sanwó tó yẹ sí koto jọba

    Ilé ìgbìmọ̀ asòfin tiń ńdú koko pé, òn yo sàmúlò ọwọ́ òfin, fi de àwọn ilésẹ́ kan tí wọ́n kọ̀ láti san àwọn owó tó yẹ sí koto ìjọba àpapọ̀.

    Alága ìgbìmọ̀ ìsúná nílé asòfin James Faleke ló sọ̀rọ̀ yí lásìkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn ilésẹ́ ìjọba nílu Abuja.

    Ó tọ́kasi pé, àjọ tón mójútó ìpéye óujẹ àti ògùn àti ilésẹ́ epo rọ̀ọ̀bì gẹ́gẹ́bí ara àwọn tíkò san on tótọ́ fún ìjọba.

    Ọgbẹni Faleke sọ pé ilésẹ́ yi lón mú kí owó tón wọlé lábẹ́lé kéré jọjọ, tó sì sọpé kò bófinmu kí àwọn ilésẹ́ yi kan ma náà owó tí kò sí nínú ètò ìsúná, tẹ́lẹ̀

    Ololade Afọnja