Yoruba

Ilese olopa nipinle oyo, ti bere igbese fifofinde lilo oko yafun yafun , siren, lona aito, lilo awon number idanimo oko ti won boo, lilo oko to ayee awako wa lowo otun tofimo oko ti eto ifonikosile re oti waye.

Eyi jeyo ninu atejade kan, eyiti agbenuso ilse olopa nipinle oyo, ogbeni olawale osifeso fowosi nilu iba.

Atejade naa nii, kikan ofin tode lilo awon oko yafun, yafun atawon ofin irinaa min yoo bere leyeosoka lati fese abo mule lawon oju opopona ipinle oyo.

atejade ohun tokasi pe, oga agba ilese olopa nipinle oyo, arabinrin ngozi onadeko to pase pe awon oga ilese olopa lekun jekun atawon to nrisi unkere -fakere oko pelu ajosepo ajo oju popo, eka tipinle oyo gbodo ridajupe ofin na rese wale botiye.

Fasasi /Idogbe

Yoruba

Ọkùnrin kan Joseph Johnson ẹni ọdún mẹ́tàlélógún ni ónkáwọ́pọ̀n sẹ́yìn níwájú ilé ẹjọ́ magisrate nípinlẹ̀ Ọsun, nílu Osogbo, láti sàlàyé on tórí labẹ̀ tó fi garu ọwọ́, lórí kíkùnà láti gba ìwé ìrìnà sílẹ̀ Canada fún oníbarà rẹ̀.

Arákùnrin yi, ni ìròyìn fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pe ó gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹdẹgbẹrin naira lọ́wọ́ Bukọla Alayande, tó sì sèlérí pé òun yó ba arábìnrin náà àti ọmọrẹ̀ gba ìwé ìrìnnà sílẹ̀ Canada.

Àmọ́ arákùnrin Johnson sọ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn, méjì lórí olèjíjà àti àilèmú ìlérí sẹ, tí wọ́n fi kan òun.

Ẹni tón mú ojú rẹ̀ balé ẹjọ́ Kayọde Adeoye náà nílu Osogbo lọ́jọ́ kẹtàlélógún osù kejìlá ọdún 2018.

Gẹ́gẹ́ bó sise wí, ìwà ọ̀hún ló tàpá sófin ìwà ọ̀daràn tìpínlẹ̀ Ọsun, nílẹ̀ yí tọdún 2002.

Bótilẹ̀jẹ́pé ẹnitómú ojú rẹ̀ balé ẹjọ́ kòwí ǹkankan nípa gbígba oníduró àmọ́ adájọ́ Modupẹ Awodele kọ̀ láti gba oníduro rẹ̀.

Tó sì ní kí ẹni tí wọ́n furasí náà, kó wà ní àhámọ́, tó sì sun ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹrìnlélógún osù- kẹsan ọdún yíì.

Kemi Ogunkọla/Sheriff Nasirudeen