Yoruba

Ọwọ́ sìnkú òfin tẹ ọkùnrin kan ńpinlẹ̀ Ọsun lórí ìwé ìrìnnà òfegè

Ọkùnrin kan Joseph Johnson ẹni ọdún mẹ́tàlélógún ni ónkáwọ́pọ̀n sẹ́yìn níwájú ilé ẹjọ́ magisrate nípinlẹ̀ Ọsun, nílu Osogbo, láti sàlàyé on tórí labẹ̀ tó fi garu ọwọ́, lórí kíkùnà láti gba ìwé ìrìnà sílẹ̀ Canada fún oníbarà rẹ̀.

Arákùnrin yi, ni ìròyìn fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pe ó gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹdẹgbẹrin naira lọ́wọ́ Bukọla Alayande, tó sì sèlérí pé òun yó ba arábìnrin náà àti ọmọrẹ̀ gba ìwé ìrìnnà sílẹ̀ Canada.

Àmọ́ arákùnrin Johnson sọ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn, méjì lórí olèjíjà àti àilèmú ìlérí sẹ, tí wọ́n fi kan òun.

Ẹni tón mú ojú rẹ̀ balé ẹjọ́ Kayọde Adeoye náà nílu Osogbo lọ́jọ́ kẹtàlélógún osù kejìlá ọdún 2018.

Gẹ́gẹ́ bó sise wí, ìwà ọ̀hún ló tàpá sófin ìwà ọ̀daràn tìpínlẹ̀ Ọsun, nílẹ̀ yí tọdún 2002.

Bótilẹ̀jẹ́pé ẹnitómú ojú rẹ̀ balé ẹjọ́ kòwí ǹkankan nípa gbígba oníduró àmọ́ adájọ́ Modupẹ Awodele kọ̀ láti gba oníduro rẹ̀.

Tó sì ní kí ẹni tí wọ́n furasí náà, kó wà ní àhámọ́, tó sì sun ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹrìnlélógún osù- kẹsan ọdún yíì.

Kemi Ogunkọla/Sheriff Nasirudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *