News Yoruba

Olórí ọmọ ológun Ibrahim Attahiru, sọpé àfojúsùn òhun ni tiridájúpé òpin débá ìwà ìgbésùmọ̀mí kóun gbogbo sì padà bọ̀ sípò lápá ìlàa-oorun ilẹ̀ yíì àtorílédé Nàijírìa lápapọ̀.

Ọgagun àgbà Attahiru sọpé ikọ̀ ọmọlóju yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ikọ̀ ọmọlógun Camaroon àti Chaad nídi fífòpin sí ìwà ìgbésùmọ̀mí.

Ó sọ̀rọ̀ yíì lásìkò tó ńbá ikọ̀ ọmọlógun sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ ajé níbùdó ńlá àwọn ọmọ-ológun Ngamdu nípinlẹ̀ Yobe.

Olórí ọmọ-ológun titun ọ̀hún níì àwọn ìpèníjà tó ńkojú ikọ̀ náà yóò jẹ́ wíwójùtu sí láipẹ.

Ọgagun Attahiru wá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀kan-òjòkan whala lẹ́ka àbóò yóò tẹnu bodò láipẹ.

Net/Idogbe

News Yoruba

Àwọn Gómìnà nípinlẹ̀ mẹ́rìn dín lógún lábẹ́ àsía ìgbìmọ̀ nílẹ̀ Nàijírìa, ni wọ́n ti sọpé àwọn kokoo, àwọn ǹkan ìrọ̀rùn tó wà fún àwọn tó kudiẹ káto fún láwùjọ pamọ́ lásìkò tí fífi òpin sí ìtànkálẹ̀ àrùn covid-19 le dandan.

 Àwọn Gómìnà ló sọ̀rọ̀ yí di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde èyí tí olórí lẹ́ka tón mójútó ọ̀rọ̀ ìròyìn, àtọ̀rọ̀ tókan àwùjọ fún ìgbìmọ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni Abudulrazaq Bello-Barkindo fisíta, lásìkò ti wọn ńfi ìhà wọn hàn sí báwọn tó ń se ìfẹ́húnúhàn se ń kó àwọn èròjà yi láwọn ìpínlẹ̀ kan lórílẹ̀ èdè yí.

 Ìgbìmọ̀ Gómìnà nílẹ̀ yí sọ pé kòsí ìpínlẹ̀ kankan ó, tó lọ́wọ́ nínú gbígbé èròjà ìrànwọ́ pamọ́ lọ́nà àitọ́.

 Wọn sì sọ̀rọ̀ ìdánilójú pé, gbogbo àwọn tó fún wọn ní ẹ̀bùn ìrànwọ́ àti ìrónilágbára sáàjú káwọn èyàn kan tó já ilé ìkẹ́rùsí, ló jẹ́ pé gbogbo rẹ̀ pátá làwọn ni àkọ́lẹ fun bóse tí n wọlé.

Ololade Afọnja

Yoruba

Orólẹ̀èdè wa Nàijírìa, ilẹ̀ olóminira Niger àti orílẹ̀èdè Chad ti ńsisẹ́ lórí àkànse ètò láti fi se àtúnse ibùdó adágún odò Chad, kí ètò ìgbáyégbádùn ba lè wà fáwọn èèyàn tó wà lágbègbè adágún odò na.

Ọga àgbà àjọ kan tí wọ́n ń pè ní National Agency for the great green wall, ọ̀mọ̀wé Bukar Hassan ló sọ̀rọ̀ yí lẹ́yìn ìpàdé kan tí wọ́n se lórí bí ilẹ̀ se ọgbẹlẹ̀, nílu New Delhi lórílẹ̀èdè India.

Ọmọwe Hassan sọ pé, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé kò sí orílẹ̀èdè tọ́rọ̀ ọ̀rọ̀ àyíká ko kan, àjọsepọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yo jẹ kí wọn lè sàtúnse sọ́rọ̀ isk àgbẹ̀ lágbayé na, bákannà ni àwọn ilẹ̀ tó ti sáà, yo di ọlọ́ra padà, tí gbe ayé yo sì túbọ̀ rọrùn fáwọn èèyàn tó wà nítòsí adágún odò Chad na.

Kemi Ogunkóla/Lara Ayọade