Yoruba

Ijoba apapo ti ngbero lati samulo apero awon Gomina fi se apinkari abere ajesara Covid-19 fawon araailu.

Be sini oni mimi kan o mii, gbedeke ojo kini osu kejila fawon osise ijoba lati gba abere Covid-19.

Alaga, igbimo iko amuseya ijoba apapa farun Covid-19, titun se akowe ijoba apapo, Ogbeni Boss Mustapha lo soro yi nilu Abuja nibi abo igbomo ohun.

O tokasi pe, pelu iranlowo awon ajo torokan ijoba apapo ti seto irolagbara fawon ibudo ayewo laboratory towa nile yii.

Ogbeni Mustapha, wa sekilo pe ayewo esi ati akosile abere ajesara yoo wa, lati fiyaje awon to ba gbe igbese naa lona aito.

Alaga igbimo iko amuseya ijoba apapo farun Covid-19 ohun, wa fowo idaniloju soya fawon eeyan ile Nigeria pe ajo eleto ilera alabode ni abere ajesara to le seto naa fun ida aadota awon eeyan ile yii titi di opin osu kini odun 2022.

Net/Elizabeth Idogbe

Yoruba

Àarẹ Muhammadu Buhari ti pàsẹ kí wọ́n ti àwọn ilé otí, àwọn ilé ijó àti àwọn ibùdó ayẹyẹ tó fi mọ́ àwọn ibùdó ìgbafẹ́ fún ọ̀sẹ̀ márun láti léè dènà ìtànkálẹ̀ àrùn COVID-19.

Ó tún pàsẹ kí wọ́n ti àwọn ilé óunjẹ ìgbàlódé nígbàtí àwọn ilé ìwé yio wà ni títì títí di ọjọ́ kejìdínlógún osù kíní ọdún 2021.

Alága ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá ìjọba àpapọ̀ lórí àrùn COVID-19, Ọ̀gbẹ́ni Boss Mustapha ló sọ̀rọ̀ yí lásìkò ìpàdé oníròyìn tí ìgbìmọ̀ náà se.

Gẹ́gẹ́bí ó se sọ, gbogbo àwọn òsìsẹ́ ìjọba láti ìpele kejìlá sísàlẹ̀ ni wọ́n ti pàsẹ kí wọ́n fìdí mọ́lé fọ́sẹ̀ márun.

Ọgbẹni Mustapha ẹnití se akswé ìjọba àpapọ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn tó ńrìn ìrìn àjò ni wọ́n ó tẹ̀lé àwọn ìlànà ààbò COVID-19 léyití ó múkí iná ètò àyẹ̀wò àti ìfimúfílẹ̀ lórí àrùn náà jó àjó rẹ̀yìn.

Yẹmisi Dada