Yoruba

Ìjọba Kéde Ìlànà Ìkánilọ́wọ́kò Tuntun Lórí Àrùn COVID-19

Àarẹ Muhammadu Buhari ti pàsẹ kí wọ́n ti àwọn ilé otí, àwọn ilé ijó àti àwọn ibùdó ayẹyẹ tó fi mọ́ àwọn ibùdó ìgbafẹ́ fún ọ̀sẹ̀ márun láti léè dènà ìtànkálẹ̀ àrùn COVID-19.

Ó tún pàsẹ kí wọ́n ti àwọn ilé óunjẹ ìgbàlódé nígbàtí àwọn ilé ìwé yio wà ni títì títí di ọjọ́ kejìdínlógún osù kíní ọdún 2021.

Alága ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá ìjọba àpapọ̀ lórí àrùn COVID-19, Ọ̀gbẹ́ni Boss Mustapha ló sọ̀rọ̀ yí lásìkò ìpàdé oníròyìn tí ìgbìmọ̀ náà se.

Gẹ́gẹ́bí ó se sọ, gbogbo àwọn òsìsẹ́ ìjọba láti ìpele kejìlá sísàlẹ̀ ni wọ́n ti pàsẹ kí wọ́n fìdí mọ́lé fọ́sẹ̀ márun.

Ọgbẹni Mustapha ẹnití se akswé ìjọba àpapọ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn tó ńrìn ìrìn àjò ni wọ́n ó tẹ̀lé àwọn ìlànà ààbò COVID-19 léyití ó múkí iná ètò àyẹ̀wò àti ìfimúfílẹ̀ lórí àrùn náà jó àjó rẹ̀yìn.

Yẹmisi Dada

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *