Yoruba

Ijọba àpapọ̀ ti sàwárí òsìsẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àtàbọ́, tójẹ́ pé ìwé ìgbanisísẹ́ ayédèrú ni wọ́n lò láti darapọ̀ mọ́ isẹ́ ìjọba.

Olórí òsìsẹ́ nílẹ̀ yí, ọ̀mọ̀wé Fọlasade Yẹmi-Ẹsan ló sọ̀rọ̀ yí di mímọ̀ nílu Abuja.

Ọmọwe Yẹmi-Ẹsan sọpé ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àwọn èyàn tí wọ́n sàwárí ní ẹ̀ka ilésẹ́ kan, tí wọ́n sì rí ẹdẹ́gbẹta òsìsẹ́ ayédèrú láwọn ẹ̀ka min, lásìkò tí wọ́n ńse àyẹ̀wò.

Olórí òsìsẹ́ nílẹ̀ yí tọ́kasi pé, àwọn òsìsẹ́ tọrọ̀ náà kàn ni wọ́n yio yọ kúrò nínú ìlànà àtẹ ìsanwó olósoosù òsìsẹ́.

Folakemi Wojuade

Yoruba

Awon osise nileese oko ojurin nile yi NRC ti bere iyanselodi ikilo olojo meta leyi to ti mu eto irinna oju irin jakejado ile yi pakaso.

Awon osise eka naa lo ti seleri wi pea won yoo pagidina igbokegbodo oko ojurin jakejado ile yi to fi mo eto irinna oju irin to gbojugboya lati ilu Ibadan silu Eko, ati Abuja si Kaduna pelu Warri si Itakpe.

Lose to koja ni egbe awon osise oko ojurin labe akoso egbe osise, ile yi NLC dunkooko pea won yoo funle iyanselodi ikilo olopa meta lati fi beere fun eto igbayegbadun won.

Ni bai na, nidi ati ma le je kiyanselodi naa o waye, alakoso eto irinna nile yi, Ogbeni Rotimi Amaechi se ipade pelu awon igbimo egbe na nilu Eko, sugbon ipade naa ko so eso rere.

Ayodele Olaopa