Ìjọba Àpapọ̀ Sàwárí Egbẹ̀rún kan Àtàbọ́ Osise Pelu Ayederu Ìwé  Igbanisise


Ijọba àpapọ̀ ti sàwárí òsìsẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àtàbọ́, tójẹ́ pé ìwé ìgbanisísẹ́ ayédèrú ni wọ́n lò láti darapọ̀ mọ́ isẹ́ ìjọba.

Olórí òsìsẹ́ nílẹ̀ yí, ọ̀mọ̀wé Fọlasade Yẹmi-Ẹsan ló sọ̀rọ̀ yí di mímọ̀ nílu Abuja.

Ọmọwe Yẹmi-Ẹsan sọpé ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àwọn èyàn tí wọ́n sàwárí ní ẹ̀ka ilésẹ́ kan, tí wọ́n sì rí ẹdẹ́gbẹta òsìsẹ́ ayédèrú láwọn ẹ̀ka min, lásìkò tí wọ́n ńse àyẹ̀wò.

Olórí òsìsẹ́ nílẹ̀ yí tọ́kasi pé, àwọn òsìsẹ́ tọrọ̀ náà kàn ni wọ́n yio yọ kúrò nínú ìlànà àtẹ ìsanwó olósoosù òsìsẹ́.

Folakemi Wojuade


Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *