Ọjọgbọn kan nínú ìmọ̀ sísàwárí epo rọ̀ọ̀bì àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìwakùsà, Olugbenga Ehinola ti késí ìjọba àpapọ̀ pe kó náwó sí ọ̀rọ̀ ìpèsè èròjà tó wọn ń pè ni Hydrocarbon èyí tí wọ́n lè ma lò dípò epo rọ̀ọ̀bì, tó sì jẹ́ pé inú àpáta ni wọ́n ti ń ríì.

Ọjọgbọn Ehinola sọ̀rọ̀ yí nígbà tó ń se àgbékalẹ̀ ìwé àpilẹ̀kọ rẹ̀ lórí isẹ́ ìwádi tó see lẹ́yìn tó gboyèe ọ̀jọ̀gbọ́n eléyi tí-í-se ìkẹtàdínláàdọ́run-ó-lé nírinwó iruẹ tí yo wáyé nílẹ̀ẹ̀kọ́ fásitì ìlú Ìbàdàn.

Ọjọgbgọn Ehinola, sọ pé, ó yẹ kí àwọn alákoso ìjọba sàmúlò àwọn ohun àlùmọ́nì tó wà nínú èròjà hydro-carbon jákèjáadò orílẹ̀èdè yi, léyi tí wọ́n le ma lòò dípò epo bẹntirolu àti afẹ́fẹ́ gaasi.

Ọjọgbọn na tún dába pé kí wọ́n se àgbékalẹ̀ ibùdó tí wọ́n ó ti ma sisẹ́ ìwádi lórí èròjà na èyí tí wọ́n ríì látara àpáta ní ẹkùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà lórílẹ̀èdè yi pin sí.

Kemi Ogunkọla/Rotimi Famakin

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *