Yoruba

Àwọn èèyàn fi èrò wọn hàn lórí àbá ètò ìsúná ọdún 2020

Àwọn akọ́sẹ́mọsẹ́ kan ti ńfi èrò wọn hàn lórí àbá ètò ìsúná ọdún 2020 tárẹ Muhammadu Buhari gbékalẹ̀ síwájú ilé ìgbìmọ̀ asòfin ilẹ̀ yíì.

Ọkan lára wọn tójẹ́ onímọ̀ lẹ́ka ètò ọrọ̀-ajé níbùdó ìwádi ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ètò ọrọ̀ àti tamúludùn NISER, nílu Ìbàdàn, ọ̀mọ̀wé Luis Chete sọpé, ìgbésẹ̀ yíyáwó kose bẹnuàtẹ́lù torípé àwọn orílẹ̀dè láwùjọ ma ǹgúnlé owó yíyá láti mú ètò ìsúná wọn dúro re.

Ọmọwe Chete wá rọ ìjọba láti mú àgbéga bá ọ̀nà tó ńgbà pawó wọlé lábẹ́léé yàtọ̀ sí yíyáwó.

Nígbà tó ńsọ̀rọ̀ lórí ewu tórọ̀mọ́ àlèkún tóbá èlé owó orí ọjà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti pawó sásùnwọ̀n ìjọba, ọ̀mọ̀wé Chete ní ìgbésẹ̀ náà yóò sàkóbá fáwọn ilésẹ́ àti àwọn tó ńpèsè ǹkan tó fimọ́ àwọn ònràjà èyí tóólè yọrísí ọ̀wọ́n gógó ọjà.

Nínú ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọn, olùkọ́ méjì lẹ́ka ọ̀gbìn àti okòòwò nílé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìbàdàn, ọ̀mọ̀wé Olubunmi Alawode àti ọ̀mọ̀wé Yetunde Ọladokun sọpé ó sepàtàkì kíjọba àpapọ̀ ridájúpé ètò ìsúnà rẹ̀ fojúsùn idàgbàsókè ilẹ̀ yíì nípasẹ̀ pípèsè isẹ́ lọ́pọ̀ yanturu.

Wọ́n wá gbóríyìn fún ìjọba tó wà lóde báyíì fún bóse sètò ìsúná rẹ̀ ọdún yíì.

Ètò ìsúná ọdún 2020 èyítí àlékún débá pẹ̀lú Trilliọnu kan àbọ̀ náirà si tọdún 2019.

Kẹmi Ogunkọla/Yẹmisi Dada      

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *