Yoruba

Gọ́mìnà Sanwoolu pàsẹ atúnse òpópónà jákèjádò ìpínlẹ̀ Èkó

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Ọ̀gbẹ́ni Babajide Sanwoolu ti pàsẹ pé kí wọ́n lọ bẹ̀rẹ̀ àtúnse àwọn ọ̀nà tó ti bàjẹ́ gidi gan, àtàwọn pópónà ńlá ńlá nígboro ìpínlẹ̀ nà, bẹ̀rẹ̀ látòní lọ.

Sanwoolu pàsẹ yi, lẹ́yìn tó ti sèpàdé pẹ̀lú iléésẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ mẹ́jọ kan tí wọ́n ní wọ́n ó gbé isẹ́ nà fun.

Bákanà ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, ti sọ pé, iléésẹ́ tó ń bójútó ọ̀rọ̀ isẹ́ òde nípinlẹ̀ Èkó, yo lọ se àtúnse àwọn ọ̀nà kéékèèké tó wà láarin àdúgbò kan sí ìkejì, tí iye wọn jẹ́ okoolelọ́gọ̀rún dínmẹ́rin láafikún sí àwọn ọ̀nà bi igba tí iléesẹ́ nà ti tún se tẹ́lẹ̀ lósù mẹ́ta sẹ́yìn.

Kẹmi Ogunkọla/Oluwayẹmisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *