Iléésẹ́ tó ń bójútó ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè ti sọ pé, irọ́ funfun báláu ni fọ́rán àwòrán kan tó wà lójú òpó ẹ̀rọ ayélúgára, èyí tó ń sàfinhàn bí àwọn kan se lọ sèkọlù sí ilé asojú ilẹ̀ Nàijírìa tó wà nílu Cotonou, lórílẹ̀dè Benin.

Agbẹnusọ fún iléésẹ́ nà, Ferdinand Nwaye, sọ pé fọ́rán àwòrán nà, jẹ́ ohun tó ti sẹlẹjẹ lọ́dún mẹ́fà sẹ́yìn, àti pé ilé asojú ilẹ̀ Nàijírìa tó wà nílu ọ̀ún wáyé lọ́dún 2013.

Ó sàlàyé síwájú pé àwọn olórí àwọn tó lọ sèkọlù sí ilé asojú Nàijírìa nígbà ni àwọn alásẹ orílẹ̀dè Senega ti mú, tí wọ́n sì jùwọ́n sẹ́wọ̀n osù mẹ́fà.

Iléésẹ́ tó ń bójútó ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè na, wá rọ́ọ̀ àwọn arálu, pé kí wọ́n máse kọbi ara síì òfegè ìròyìn tí àwọn èèyàn wọ̀nyí ńgbé kiri tó sì jẹ́ pé, wọ́n mọọrọ n sebẹ ni, láti fi lè dáà àarin ilẹ̀ Nàijírìa àti ilẹ̀ Bẹnin rúù.

Kẹmi Ogunkọla/Oluwayẹmisi Dada

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *