Yoruba

Ilé Ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti gbé ìgbẹ́jọ́ kalẹ̀ lórí ẹjọ́ àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti da ìgbẹ́jọ́ ìgbẹ́jọ́ ilé ẹjọ́ gíga tí ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ gbé kalẹ̀ tó ka ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ lápákò láti júwe ilé fún àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ nù.

Ilé ẹjọ́ náà ní ìgbẹ́jọ́ tí ilé ẹjọ́ gíga gbé kalẹ̀ ni wọ́n gbé lórí ountí wọ́n lérò léyi tí wọ́n kò lee gbà wọlé.

Nínú ìdájọ́ tí onídajọ́ Haruna Tsammani kà, ó ní ó ní kò sí ẹ̀rí láti gbe ẹjọ́ ìgbésẹ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ yi lẹ́sẹ̀ lásìkò ti àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ pe ẹjọ́ náà lọ́dún tó kọjá.

Àmọ́ sá ilé ẹjọ́ náà sọ ni pàtó bóyá ìjọba ìpínlẹ̀ yi lágbára láti yọ àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tí wọn dìbò yàn tàbí bẹ́ẹ̀kọ lèyí tí ó ní ilé ẹjọ́ gíga ti pinlẹ̀ yi gbé ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ kà.

Lósù karun ọdún tó kọjá ni àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ lọ síwájú ilé ẹjọ́ gíga tìpínlẹ̀ yi láti ká ìjọba lọ́wọ́kọ́ láti máse yọ wọ́n nípò léyi tí ilé ẹjọ fọwọ́sí wípé ìjọba ìpínlẹ̀ yi kò lágbára láti yọ àwọn alága tí wọ́n dìbò yàn kúrò nípò.

Sunday Ogunyẹmi/Dada Yẹmisi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *