Ilésẹ́ ọmọ ológun òfurúfú sọpé àwọn ti pàdánù, obìrin àkọ́kọ́ tó ńwa ọkọ̀ báàlù ìjagun ọ̀gágun Tolulọpẹ Arotile, nínú ìjàmbá ọkọ̀ kan tówáyé nílu Kaduna.
Ọga àgbà lẹ́ka ìròyìn nílesẹ́ ọ̀hún, ọ̀gágun Ibikunle Daramọla, kéede ìpapòdà ọ̀gágun Arotile nínú àtẹ̀jáde kan nílu Abuja.
Ológbe ọ̀hún ló gba àgbéga lọ́dún tókọjá, látọwọ́ ọ̀gágun àgbà Saddique Abubakara nílu Abuja.
Àtẹ̀jáde náà sàlàyé pé ọ̀gágun Arotile jẹ́ Ọlọrun nípè lána òdeyíì, lẹ́yìn tóò forípaa níbi ìjàmbáọkọ̀ ọ̀hún.
Títí tófijẹ́ Ọlọ́run nípè, ọ̀gágun Arotile ẹnitó jẹ́ bíbúrafún lósù kẹsan ọdún 2017, tósìjẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tó ńwa ọkọ̀ báàlù ìjagun lájọ náà.
Èwẹ̀, ọ̀gágun àgbà Sadique Abubakar lórúkọ àwọn òsìsẹ́ tóòkù bá àwọn ẹbí ọ̀gágun Arotile kẹ́dùn tósì gbàdúrà ìtùnúù fẹ́bí ọ̀hún.
Elizabeth Idogbe