Yoruba

Ayewo Fihan pe Gomina Ipinle Ekiti ti ni Arun Covid-19

Gomina ipinle Ekiti, Omowe Kayode Fayemi ni ayewo ti fidi e mu’le pe oun ni arun Coronavirus.

Gomina Fayemi lo je koro yi di mimo lori opo ero ayelujara abeyefo re, pe ayewo eleeketa ti won se fun ni abajade re so pe oun ni arun naa lana.

Gomina loti lo y’ara re soto fun itoju pelu awon iko ilera t’oje t’ijoba.

Pelu isele yi, Gomina Fayemi ti ya awon ise to se koko, s’oto ki igbakeji Gomina, Otunba Bisi Egbeyemi l’ati tesiwaju ninu ise oba.

Babatunde Salaudeen/Oriola Afolabi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *