Religious

Àarẹ Mùsùlùmí gba àwọn eeyán nímọ̀ràn lórí ìlànà áàbò lásìkò ọdún iléyá

Sáàjú ọdún iláyá, áàrẹ mùsùlùmí fún gbogbo ilẹ̀ yorùbá, Ẹdó àti Dẹlta, Àlhájì Daud Akinsọla ti gba àwọn mùsùlùmí lámọ̀ràn láti tẹ̀lé gbogbo àwọn ìlànà áàbò láti dènà àrùn covid-19 láwọn ibùdó ìjọsìn.

Àarẹ fọ̀rọ̀ àmọ̀nràn yi síta nígbàtí ó ńgba àwọn ikọ̀ àjọ tó ńrísí ìtanijí ará ìlú sí ojúse wọn, NOA, ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ lálejò nílé rẹ̀ nílu ìbàdàn .

Àlhájì Akinsọla ẹnití bí ìsòro tán àrùn coronavirus nílẹ̀ yí se ǹka lóminú wá rọ àwọn mùsùlùmí láti kírun ọdún wọn láwọn mọ́sálásí jímọ̀h tó sún mọ́ wọn, kí wọ́n lo ìbòmú, fọ ọwọ́ wọn àti kí wọ́n yàgò fún ìfarakínra.

Sáàjú ni ọ̀gá àgbà àjọ NOA, nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ Arábìnrin Dọlapọ Dosumu ti ní èrèdí àbẹ̀wò wọn ni láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé isẹ́ àarẹ mùsùlùmí láti la àwọn mùsùlùmí lọ́yẹ̀ lórí pàtàkì tí tẹ̀lé ìlànà áàbò covid-19 lásìkò ọdún.

Arábìnrin Dosumu wá késí àwọn asájú ẹ̀sìn láti máà tẹ̀síwájú láti kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn ní pàtàkì lílò ìbòmú àti títakété síra ẹni láti pinwọ́ àtànkálẹ̀ àrùn covid-19

Dada Yẹmisi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *