Politics

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ buwọ́lu àtúnse àbáòfin ètò ìsúná

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ ti buwọ́lu àtúnse àbá ìsúná ọdún 2020 tí ìpínlẹ̀ yi tí àdínkù dé bá sí biliọnu mẹ́rìnléladọsan, 174 billiọn.

Ìgbésẹ̀ yi ni wọn gbé lẹ́yìn tí wọ́n ti káà fún ìgbà kẹta níbi ìjóko ilé èyítí adarí ilé, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin darí rẹ̀.

Àbá ètò ìsúná ọdún 2020 ni ilé ìgbìmọ̀ asòfin sàtúnse rẹ̀ láti igba billiọnu ó dín mẹ́jọ 208 billion sí billiọnu mẹ́rìnléláàdọsan, 174 billion naira.

Gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ ti alága ìgbìmọ̀ tẹ́ẹ̀kótó ilé lórí owó ìlú àti ìsúná, ọ̀gbẹ́ni Akeem Mustapha kà, àtúnse náà ni ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹbẹ ẹ̀ka alásẹ ìjọba láti mú àdínkù bá àbá ètò ìsúná ọ̀ún.

Dada Yẹmisi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *