Yoruba

Àwọn awàkọ̀ bèrè fún ìdásí ìjọba lórí àlékún owó epo petirolu

Ọpọ àwọn ilé-epo tó wà ní gbóòro ilù ìbàdàn, lógbé ilé epo wọn tì pa lóòrọ òní, nítorí bẹ́gbẹ́ àwọn alágbàtà epobẹtirolu nílẹ̀ yíì, se kéde pé kíwọ́n máà ta èròjà náà kọjá ogóje naira àti naira mẹ́ta tíwọ́n ní kíwọ́n ó máà ta.

Akkọ̀ròyìn ilé-isẹ́ wa, tó tọpinpin bọ́rọ̀ serí láàrin ìgbóòro ìlú ìbàdàn, jábọ̀ pé, ìwọnba diẹ àwọn ilé-epo tó sí sílẹ̀, ló ńta jálá epo bẹtirolu kan ni aadọta naira ódín naira méjì àtáàdọta kọ́bọ̀ fáwọn oníbarà.

Bẹ́ẹ̀ ló tún sọ́ọ̀di mímọ̀ pe, àwọn alagbọta epo kan sí ńta tíwọn lógeje naira ólé naira mkta, tó jẹ́ iye tíwọ́n ní kíwọ́n máà ta gan bíotilẹ̀ jẹ́pé pẹ̀lú itoo àtò dabọ làwọn oníbarà fi ńra.

Diẹ lára àwọn awakọ̀ tófimọ́wọn awakọ̀ èrò tó bóníròyìn ilé-isẹ́ wa sọ̀rọ̀, lórí owó orí epo tuntun náà, késí ìjọba àpapọ̀ láti dásọ́rọ̀ náà, kí ìdẹ̀kùn léè baráàlu lẹ́nu ìsòro tíwọ́n ńkojú lákoko àrùn covid 19

Wojuade Fọlakẹmi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *