Imaam àgbà Mọ́sálásí Oluyọle, Sheik Mudasiru Badda ti lon ńfẹ́ káwọn èèyàn àwùjọ máà sọ́raséè, torípé ẹ̀dá kan ọmọ ìgbà àti àkọ́kọ́ tí wọ́n yóò kun lóòkè èpẹ̀.

Imam Baddah sọ èyí níbi ètò adua ogójì ọjọ́ Gómìnà tẹ́lẹ̀ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, Sẹ́nátọ̀ Ishaq Abiola Ajimọbi.

Ó sàlàyé pé, Sẹnetọ Ajimọbi gbé ìgbé-ayé tóò làmìlaka tófimọ́ sisisẹ sin ọmọnìyàn, tósì yẹ káwọn èèyàn wóò àwòkọ́se rẹ̀.

Nínú wáàsi tiẹ níbi ètò adua ogójì ọjọ́, oní wássi àgbáyé, Àlháji Muideen Bello, sàlàyé ìdí tó fi se pàtàkì fáwọn èèyàn láti gbá ìgbé ayé wọn pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ti yóò jẹ rírántí lẹ́yìn ìpapòdà kóowá.

Alhaji Bello kò sài wá rọ àwọn ọmọ-ológbe láti wo àwòkọ́se bàbá wọn.

Ètò adua ogójì ọjọ́ ológbe Abiọla Ajimọbi láwọn èkàn nílẹ̀ yíì péjú-pẹ́sẹ̀ síì.

Wojuade Fọlakẹmi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *