Alákoso fétò ìlera nípinlẹ̀ Èkó, ọ̀jọ̀gbọ́n Akin Abayọmi ní àyẹ̀wò ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ótiní àrùn covid-19.

Alákoso fétò ìròyìn àti ọ̀rọ̀ àwùjọ nípinlẹ̀ Èkó Gbenga Ọmọtọshọ ló jẹ́ kọ́rọ̀ yí di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fisíta lorọ òní.

Àtẹ̀jáde náà tọ́kasi pé ọ̀jọ̀gbọ́n Abayọmi, ló mọ̀ pé òun tiní àrùn yi lẹ́yìn tí àyẹ̀wò tí wọn gùnlé lórí gbogbo àwọn tó ti farakínra pẹ̀lú ẹni tó ní àisàn yi, wáyé, àtẹ̀jáde fikun pé ko ti ni àmì ara kankan.

Níbàyínáà, àjọ tón gbógunti ìtànkálẹ̀ àrùn nílẹ̀ yí NCDC, lálẹ̀ àná fìdí ẹ̀múlẹ̀ pé àwọn èyàn ọ̀dúnrún lé méjìlélógún tintún tápapọ̀ àwọn tó ti ní àrùn covid -19 nílẹ̀ Nàijírìa sì lé ní ẹgbẹ̀rún méjì lé ládọta Ọlọlade Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *