Yoruba

Olósèlú kan ńfẹ́ kí òfin wà lórí ipèsè isẹ́ fáwọn ọ̀dọ́

Ó yẹ kí ilé ìgbìmọ̀ asòfin gbé òfin ìjọba ìpínlẹ̀ láti pèsè isẹ́ fún ọ̀dọ́ tó bá ti pé ọdún mọ̀kànlélógún.

Ọrọ yí ló tẹnu, olósèlú títún se olùdarí kan, ọ̀mọ̀wé Fọla Akinọsun jáde lásìkò tón kópa lórí ètò kan Premier F.M, tí wọ́n pè ní “The Stage”.

Ọmọwe Akiọsun sọ pé ìjọba ní láti wáse fún ọ̀dọ́ láti ìgbà tí wọ́n kéré kí wọ́n lè yàgò fún nílọ́wọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́.

Ọmọwe Akinọsun wá gba ìjọba ní gbogbo ẹ̀ka níyànjú láti pèsè òpòpónà tó dára tó sì lujára, kétò ọ̀rọ̀ ajé lè rúgọ́gọ́ si.

Ó tọ́kasi pé, òun tín ró àwọn ọ̀dọ́ lágbára pẹ̀lú oníruru isẹ́ ọwọ́, kólè jẹ́ ara ipa tí òun sá nídi ìdàgbàsópè ilẹ̀ Nàijírìa.

Ọlọlade Afọnja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *