Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ yóò sàyẹ̀wò fáwọn òsìsẹ́ àjọ elétò ìdìbò ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, OYSIẸC, gẹ́gẹ́ bí ètò ìgbaradì fún ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tí yóò wáyé láipẹ.

Gómìnà Seyi Makinde forúkọ àwọn osojú àjọ OYSIẸC náà sọwọ́ síì ilé, tí ósì jẹ́ kíkà fún ilé nípasẹ̀ adarí ilé, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin.

Orúkọ àwọn mẹ́jọ tí yóò léwájú àjọ OYSIẸC, ni ọ̀gbẹ́ni Isiaka Ọlagunju, gẹ́gẹ́ bí alága, nígbàtí ọ̀gbẹ́ni Adeniyi Afeez Babatunde, àlhájà Ganiyat Saka, ọ̀gbẹ́ni Ọlarenwaju Emmanuel, ọ̀gbẹ́ni Kunle Agboola, ọ̀gbẹ́ni Rẹmi Ayọade, ọ̀gbẹ́ni Sunday Falana àti ọ̀gbẹ́ni Adeọjọ Elias jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́.

Adarí ilé wáà rọ àwọn èèyàn ọ̀hún láti fíì ilé tó ńso nípa wọn, c.v, sọwọ́ sílé ópẹ́jù òní yíì, láti fáwọn asòfin láàye láti mọ ohun yóòyẹ nípa wọn.

Elizabeth Idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *