Yoruba

Gomina Ipinle Oyo Seleri Eto Idibo Ijoba Ibile Ti Ko Ni Le Ja N Bakan

Gomina Ipinle Oyo, Onimo Ero Seyi Makinde ti sodi mimo pe, awon iranse tawon yoo lo nibi eto idibo ti yoo wa lawon Ijoba Ibile, nipinle yii, kii se lati fi tako eto tawon oludibo ni lati fidibo. 

Nibi eto ibura fawon omo Igbimo tuntun fajo eleto idibo Ipinle Oyo, OYSIEC, ni Gomina ti soro yii di mimo, pelu alaye pe, Erongba Ajo OYSIEC naa ni lati seto idibo ti ko ni leja n bakan ninu, ti yoo si lo niroworese lawon ijoba ibile meteeta-lelogbon gege bofin ile yi se lakale.

O wa ro awon eeyan to n gbaradi saaju awon eto idibo odun 2023 lati fun rawon lomi suuru mu, kiwon si lafoju sun lori awon eyi to wanle lowo bayi.  Nigba to n soro loruko Ajo eleto idibo Ipinle Oyo, Alaga Ajo ohun, Ogbeni Isiaka Olagunju seleri pea won yoo sise awon gege bi ise igbimo tuntun tiwon yan fajo eleto idibo ipinle Oyo, naa OYSIEC niwon je igbimo elenu mejo.

Folakemi Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *