Yoruba

Ileese Olopa Fofin De Lilo Bibo Oko Nitori Eto Idibo Ipinle Edo

Saaju eto idibo Gomina ti yoo waye lola nipinle Edo, oga agba yanyan funleese Olopa ile yi, Ogbeni Mohammed Adamu ti pase pe ki opin ba igbokegbode oko nipinle naa lati oru oni titi di aago mefa irole ola.

Ninu atejade ti agbenuso ileese Olopa ile yi DCP Frank Mba fi sita ni Oga Agba ileese Olopa ti soo di mimo wipe igbese naa sepataki nitori ati dena lilo bibo pelu inkan ija oloro ati egboogi olowo, ati lati ko awon janduku oselu lapapo

Oga Agba ileese Olopa war o gbogbo eeyan Ipinle naa pe ki won tu yaayaa jade lojo idibo lati dibo fun eni to wu won, o tun salaye wipe ileese Olopa ati gbogbo awon eleto aabo to ku lo ti wa ni igbaradi lona ati je kalaafia joba.

O sekilo wipe awon agbofinro ko ni faaye gba jagidijagan Kankan tabi igbese jiji apoti ibo gbe pelu tabo-rabo, to fi mo sisoro kobakungbe sira eni pelu gbogbo iwa yoowu to ba ke pagidina ijagara eto idibo naa.

Babatunde

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *