Yoruba

Àwọn ọ̀dọ́ yarí kanlẹ̀ nípinlẹ̀ Ògùn wọ́n ní dandan kí kọ̀lọ̀pa fòpin sí fìyàjẹ ni

Àwọn ọ̀dọ́ tó ń se ìfẹ̀húnúhàn tako ikọ̀ ọlọ́pa SARS nípinlẹ̀ Ògùn ti fẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ikọ̀ ọlọ́pa náà tíjọba ti fòfindè sí ń dúnkokò mọ́ àwọn èèyàn kan nípinlẹ̀ náà.

Àwọn ọ̀dọ́ tó ń fẹ̀húnú hàn náà tí wọ́n se ìwọ́de wọ́ọ̀rọ́ wọ́ lọ sí ọ́fìsì Gómìnà nílu Abẹokuta tún fi ilodi sí wọn hàn sí ikọ̀ ọlọ́pa tuntun tí wọ́n fún pé sí “SWAT” pẹ̀lú bí wọ́n se sàpèjúwe rẹ̀ wípé bí ìjọba ti wọn kan pá orukọ da ni.

Àwọn tó ń flhúnúhàn náà ló gbé àkọlé lórísirísi lọ́wọ́.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lọ́rúkọ àwọn yóòkù rẹ̀, ọ̀gbẹ́ni Ọlaolu David sàlàyé wípé àwọn ọmọ ikọ̀ SARS tí wọ́n ti fòfindè náà ló tún fìyàjẹ àwọn ọ̀dọ́ kan lágbègbè Oníkólóbó nílu Abẹokuta pẹ̀lú agbègbè Àkútè-Ajurin àtàwọn agbègbè min lópopona ìlú Èkó sípinlẹ̀ Ògùn.

Ọgbéni David wá késíjọba pé kí wọ́n tètè gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti dènà ìwà àsejù àwọn ikọ̀ ọlọ́pa yi lórílẹ̀èdè yí pẹ̀lú àlàyé wípé báwọn ọlọ́pa se ń dúnkokò pẹ̀lú ìfìyàjẹni fi kọù àwọn ọ̀dọ́ ló lú se ìpalára fún ọjọ́ ọ̀la wọn.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn ọmọọba Dapọ Abiọdun ráwọ ẹ̀bẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́ tó ń fẹ̀húnúhàn náà wípé kí wọ́n fẹ̀sẹ̀ se, àti pé kí wọ́n fààyè gbé ìjọba àpapọ̀ láti se àtúntò iléèsẹ́ ọlọ́pa ill yí.

Ní bai ná, agbẹnusọ iléésẹ́ ọlọ́pa ìpínlẹ̀ Ògùn, ọ̀gbẹ́ni Abiọdun Oyeyẹmi ti sàpèjúwe ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn ikọ̀ SARS pé wọ́n sì ń sese gẹ́gẹ́ bí irọ́ tó jìnnà sóòtọ.

Salaudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *