Àjọ tó ńrísí ọ̀rọ̀ àwọn ajagun fẹ̀yìntì nílẹ̀ yíì, MPB, sọpé irọ́ tó jína sóòtọ láhesọ ọ̀rọ̀ tó ńjà ràiràn pé àjọ náà yóò bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò ìwé ẹ̀rífáwọn ọmọ ẹgbẹ́ látọ jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n osù kọkànlá sí ọjọ́ kẹsan osù kejìlá.

Èyí jẹyọ nínú àtẹ̀jáde tálukoro àjọ MPB, ọ̀gágun Ọlayinka Lawal fisíta tó sì rọ àwọn ajagun fẹ̀yìntì láti kọtí ọ̀gbọi sí ìròyìn òfeegè náà.

Àtẹ̀jáde náà fidirẹ múlẹ̀ pé, ọ̀rọ̀ náà ni àwọn oníròyìn òfegè ọ̀hún gbé láti ojú òpóò ẹ̀rọ ayélujára ìwé-ìròyìn kan, èyí tówáyé lọ́dún 2017, lásìkò tí ìgbésẹ̀ àyẹ̀wò wáyé nígbanà lọ́un.

Ọgagun Ọlayinka Lawal wá sàlàyé pé, ìgbésẹ̀ ti ńlọ lọ́wọ́ láti sàyẹ̀wò ìwé-ẹ̀rí fáwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà àmọ́ ìgbà àti àkókò koti jẹ́ kíkéde tó sì gbàwọ́n níyànjú láti fọọkànbalẹ̀ pẹ̀lú àlàyé pé àjọ náà yóò fi ìgbà yoowu tígbesẹ̀ náà yóò ba wáyé tóò wọn létí.

Fasasi/Idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *