Olùdarí àjọ ẹ̀sọ́ ojú pópó nílẹ̀ yíì, FRSC, ẹ̀ka nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, arábìnrin Uche Chukwurah sọ pé, àkọsílẹ̀ àwọn ìjàmbá ọkọ̀ ojú pópó tajọ náà se láàrin osù keje sósù kẹsan ọdún yíì, ti pọ̀jù, èyí tó se nígbà tí ọdún yíì dá sí méjì lọ, tí se méjìléladọfa.

Arábìnrin Chukwurah tó sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ lákokò tón báwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí àwọn akitiyan tíwọ́n ti làkalẹ̀ fáyajọ́ àwọn ẹ̀sọ́ ojú pópó nílẹ̀ adúláwọ̀ fún tọdún 2020 tí tún se ọjọ́ ìrántí àwọn èèyàn tó ti lùgbàdì àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá kan tàbómin-láwọn ojú pópó lágbayé, sàlàyé pé, àkókò òjò àteré àsá pajúdé àwọn awakọ̀ kan, ló sokùnfà àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá náà.

Kò sài fikun pé, láàrin àkókò ọ̀hún bi méjìlélógóje ni iye ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá tájọ náà se àkọsílẹ̀ rẹ̀ àti àdọ́rin àwọn èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn, láárin osù keje sósù kẹsan ọdún yíì.

Ó wá rọ àwọn awakọ̀ láti yàgò kúrò nídi àwọn àlòkù táyà ọkọ̀, èyí tó lè máà sàkóbá fún wọn.

Kehinde/Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *