Àarẹ orílẹ̀dè yíì Muhammadu Buhari ti ké sáwọn àjọ tọ́rọkàn lẹ́ka ètò ọ̀gbìn láti lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ sáwọn ìlànà ètò ọ̀gbìn ìgbàlódé lẹ́ka náà.

 Ìlú Abuja láarẹ ti sísọ lójú ọ̀rọ̀ yíì lákokò tón sèfilọ́lẹ̀ ètò kan tóníse pẹ̀láwọn àgbẹ̀ òde ìwòyí, èyí tẹ́ka tónrísí ìdàgbásókè ilẹ̀ ọ̀gbìn sagbátẹrù rẹ̀, láti lè jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ túbọ̀ máà fìfẹ́ hàn sí isẹ́ àgbẹ̀.

Ó wá mú dáwọn ọ̀dọ́ tó bá nífẹ sísẹ́ àgbẹ̀ náà lójú pé, òun yóò pèsè àyíká tó rọrùn, fún kíkópa wọn.

Àarẹ Buhari kò sài sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, igi lẹ́yìn ọgbà ẹ̀ka ètò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ Nàijírìa sìni isẹ́ ọ̀gbìn jẹ́, nítorí bó se jẹ́ ẹ̀ka kan gbogi tó ń pèsè àwọn ǹnkan tó pọ̀jù lórí iye owó tíwọ́n ńpa, lórí àwọn ọjà tíwọ́n ǹpèsè lábẹ́lé.

Ó wá fìrètí rẹ̀ hàn pé sísàgbénde NALDA, yóò mú kóunjẹ pọ̀ lọ́pọ̀yanturu nílẹ̀ Nàijírìa, tíwọn yóò sì máà rówó pawọlé lábẹ́lé látara àwọn óunjẹ tíwọ́n bá ńtà sáwọn ilẹ̀ òkèrè, nígbà ta bá fi rọ́dún diẹ sákokò tawà yíì.

Net/Wojuade 

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *