Yoruba

Asájú Nínú Ẹgbẹ́ Òsèlú PDP, Ńfẹ́ Kíjọba Àpapọ̀ Sọ́ra Se, Lórí Fífi Òfin De Lílò Ojú Òpó Ayélujára Ìbánidọ́rẹ

Àwọn asájú ẹgbẹ́ òsòlú Peoples Democratic Party, PDP, lẹ́kùn ìwọ̀orùn gúsù ti yan ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni márun, láti parí áwọ̀ tó wà lárin àwọn igun kan, lẹ́kùn náà.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọsun, ọmọ ọba Olagunsoye Oyinlọla ni olórí ìgbìmọ̀ ọ̀hún.

Nínú àtẹ̀jáde tí akọ̀wé àgbà, lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde, ọ̀gbẹ́ni Taiwo Adisa fisíta, tọ́kasi pé, àwọn asájú ẹgbẹ́ yi ni wọ́n se ìpàdé nílé ìjọba tó wà lágodi nílu ìbàdàn.

Àwọn asájú ẹgbẹ́ òsèlú PDP, fi àsìkò náà késí ìjọba àpapọ̀ àti ilé ìgbìmọ̀ asòfin láti se àtúngbéyẹ̀wò àbá, fífi òfin de lílò ojú òpó ìbánidọ́rẹ ayélujára, pẹ̀lú àlàyé pé, irúfẹ́ ìgbésẹ̀ yi ni yo dènà ẹ̀tọ́ àwọn èyàn ilẹ̀ yí láti sọ̀rọ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ Gómìnà Seyi Makinde, ó pè fún ìsọ̀kan nínú ẹgbẹ́ pẹ̀lú àtẹnumọ́ pé, PDP, lẹ́kùn ìwọ̀ orùn gúsù, gbọ́dọ̀ ma léwájú, kí wọ́n si jẹ àwòkọ́se.

Iyabọ Adebisi/Ọlọlade Afọnja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *