Ìjọba àpapọ̀ tin kọminú bí iye àwọn tóní àisàn iba ọ̀rẹ̀rẹ̀ seń pọ̀si láwọn ìpínlẹ̀ kọ̀kan.

Alákoso fétò ìlera, Dókítà Ọlọrunnibẹ Mamora ló fìdí ọ̀rọ̀ yí múlẹ̀ nílu Abuja pẹ̀lú àtọ́katí pé pẹ̀lú bí àsìkò ẹ̀rùn se ń wọlé dé, wọ́n ti ń fi ìdí ìsẹ̀lẹ̀ àisàn náà múlẹ̀ láwọn ìpínlẹ̀ kọ̀kan nílẹ̀ yí.

Alákoso sàlàyé pé ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta àwọn tó ti ní, tí wọ́n sìti se ìtọ́jú fún tí wọ́n  ti móríbọ́ àmọ́ kò dín ní àwọn èyàn ẹgbẹ̀rún méjì tí wọ́n sin gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nínú ilé àti nílé wòsàn.

Dókítà Mamora tọ́kasi pé, ẹ̀ka ètò ìlera tẹpẹlẹ mọ́ síse ìtajú ẹni tó ní ìpèníjà lórí ìlera wọn, tó sì fikun pé ìjọba ńtiraka láti ri dájú pé, wọ́n sisẹ́ láti fòpin sí ìtànkálẹ̀ àisàn yí àtàwọn àrùn miràn, tó ń dún koko mọ́ ìlera àwọn èyàn nílẹ̀ Nàijírìa.

Aminat Ajibikẹ/Ọlọlade Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *