Ìjọba àpapọ̀ sọ pé, ó ti pa dandan báyi láti fẹsẹ̀ ìgbọkànlé múlẹ̀ daindain láàrin ìjọba àti arálu, lẹ́yìn ìfẹ̀húnúhàn fífi òpin sí ẹ̀ka Sars.

Igbákejì àrẹ, ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Ọinbajo ló sọ̀rọ̀ yí lásìkò àkànse ètò láti se àtúnse on tó bàjẹ́ nípinlẹ̀ Èkó èyí tí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó se àgbékalẹ̀ rẹ̀ ní Ìkẹjà.

Ọjọgbọn Ọsinbajo sọ pé yio dára tí ìjọba ní gbogbo ẹ̀ka bá sisẹ́ láti da ìgbọnkànlé táràlú ní nínú ìjọba, padà láti lè dènà irúfẹ́ bíba dúkia arálu jẹ́, èyí tó wáyé láipẹ yí nílẹ̀ Nàijírìa.

Igbákajì àrẹ sàpèjúwe bíba dúkia ìjọba tó jẹ́ tarálu jẹ́, gẹ́gẹ́bí èyí tó kudiẹ káto, tí yo sì mú ìfàsẹ́yìn débá ilẹ̀ yí pẹ̀lú àfikún pé ọ̀pọ̀ owó tón wọlé nílẹ̀ yí tí kiise látara epo rọ̀ọ̀bì, ló wá láti ìpínlẹ̀ Èkó, ó wá rọ oníkọ̀jukọ̀ láti se àtúnse tó yẹ, kíyì àti ẹ̀yẹ ilẹ̀ yí lè jẹ́ dídá padà.

Ajibike/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *