Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ bu ẹnu àtẹlu àbọ̀ ìròyìn ilésẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ CNN lórí ìsẹ̀lẹ̀ ìbọn yínyìn ládugbò Lẹ́kkí

Alákoso fọ́rọ̀ ìròyìn àti àsàà, Lai Mohammed ti sọ̀rọ̀ lórí àbọ̀ ìwádi lórí ìbọn yínyìn tó wáyé lógúnjọ́ osù kẹwa lágbègbè Lẹ́kkí, èyí tí ilésẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ nílẹ̀ America CNN, gbé síta.

Ọgbẹni Mohammed sàpèjúwe àbọ̀ ọ̀hún gẹ́gẹ́bí èyí tó fíì sojukan , tí kò sì sọ bí ọ̀rọ̀ ti rí gan, bákanà ló sọpé èyí tí ilésẹ́ BBC, gbé síta ló fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ jùlọ.

Alákoso sọpé ilésẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ CNN, ló yẹ kí wọ́n fọwọ́ òfin mú lórí ìròyìn tí ón síì arálu lanà tí wọ́n gbé síta, wípé ológun yìnbọn mọ́ arálu.

Ó wá rọ àwọn èyàn àwùjọ tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé, wọ́n se básubàsu àti mọ̀lẹ́bí àwọn èyàn tí wọ́n sọpé, wọ́n ńwá láti fẹjọ́ sùn ìgbìmọ̀ tí wọ́n gbé kalẹ̀ lẹ́ka ètò ìdájọ́.

Ó fikún pé, ìròyìn tí ilésẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ CNN, gbé síta, ni kò sàfihàn ogunlọ́gọ̀ ǹkan ìní ìjọba tó jẹ́ bíbàjẹ́, ó wá tẹnumọ pé àwọn òsìsẹ́ ètò àbò ló yẹ kí wọ́n gbóríyìn fún, dípò bíbu ẹnu àtẹ́ lù wọ́n.

Adesanya Blessing/Afọnja Ọlọlade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *