Yoruba

Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Nípinlẹ̀ Èkó Gbé Ìgbésẹ̀ Láti Sètò Ìrànwọ́ Fáwọn Tó Fara Kásá Lásìkò Ìfẹ̀húnúhàn #EndSARS

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin nípinlẹ̀ Èkó ti lọ rí lára àwọn tí wọ́n fura pé, wọ́n fara kásá lásìkò ìfẹ̀húnúhàn Endsars láti lè mọ pàtó ètò ìrànwọ́n tí wọ́n yo se fún wọn.

Igbákejì adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin, Ọ̀gbẹ́ni Wasiu Ẹshinlokun-Sanni, ló jẹ́ kọ́rọ̀ yí di mímọ̀, lásìkò ìjọko ilé ọlọ́jọ́ mẹ́ta pàtàkì láti mọ àwọn on pàtó tó bàjẹ́ lásìkò ìfẹ̀húnúhàn #EndSARS nípinlẹ̀ Èkó.

Ó se lálàyé pé pàtó ìjóko yi, láti mú kí ìbágbépọ̀ àláfìa wà lárin àwọn èyàn àwùjọ, tó fimọ́ sísètò ìrànwọ́ fáwọn tó fara kásá ìfẹ̀húnúhàn ọ̀hún.

Ẹjẹ́ka muwá sírantíyín pé, adarí ilé, ọ̀gbẹ́ni Mudashiru Ọbasa, lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n osù tó kọjá, ló gbé ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mksan kalẹ̀ èyí tí Ẹshinlokun-Sanni lé wájú rẹ̀.

Ìgbìmọ̀ shún ló sèwádi ibi tin kan bàjẹ́ dé àti iye àwọn ẹni tó tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù ẹ̀míwọn, láti lè sètò ìrànwọ́ tóyẹ fún wọn.

Amos Ogunrinde/Afọnja Ọlọlade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *