Yoruba

Àjọ NYSC Kìlọ̀ Lórí Lílo Asọ Ẹgbẹ́jọdá Àwọn Àgùnbánirọ̀

Àjọ tó rísí ọ̀rọ̀ àwọn àgùnbánirọ̀ NYSC, fẹ́ kí àwọn tó ńya cinema máà gbàsẹ tó yẹ kí wan tó lo asọ ẹgbẹ́ jọdá àwọn àgùnbánirọ̀ nínú àwọn cinema wọn.

Igbákejì ọ̀gá àgbà àjọ náà fọ̀rọ̀ tó jẹmọ tó fin, ọ̀gbẹ́ni Christian Oru ló sọ̀rọ̀ yí nilu Èkó lásìkò tó ńsèpàdépọ̀ pẹ̀lú àjọ tó ńrísí ipeniye àwọn cinema nílẹ̀ yí àti àwọn tọ́rọ̀ kàn ní agbo amúludùn.

Ọga àjọ NYSC ní lílo asọ ẹgbẹ́jọdá àwọn àgùnbánirọ̀ lọ́nà tí òbófin mu nínú àwọn cinema ni àwọn alásẹ àjọ náà ó ní faramọ́.

Ọgbẹni Oru sáláyé pé, kí wọ́n tó lo asọ yi, àwọn tó ńya cinema gbọ́dọ̀ kọ̀wé láti gba àsẹ, tí wọ́n yio sì so ni pàtó ohunti wọ́n fẹ́ lóò fún àti wípé wọ́n gbọ́dọ̀ fẹ̀mí ìmọrírì hàn sájọ NYSC, nínú cinema náà.

Gẹ́gẹ́bí ó se sọ, àjọ NYSC ti setán láti yáàyè gba àwọn tó ńse cinema láti polówó àwọn eré wọn láwọn ọgbọ́ ìfiniwọ̀ àwọn àgùnbánirọ̀ gbogbo.

Net/Yẹmisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *