Níbàyí  náà, kò ti si àisàn ibà pọ́njú ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ tàbí nílé ìwòsàn ẹ̀kẹ́sẹ́ ìsègùn UCH, nílu Ìbàdàn.

Ọga àgbà ilé ìwòsàn náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Jesse Ọtẹgbayọ ló sọ̀rọ̀ yí níbi ìpàdé oníròyìn tó wáyé nílu Ìbàdàn.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọtẹgbayọ ẹnití ó sàlàyé wípé àisàn yí ló wọ́pọ̀ ní áàrin gùngùn ilẹ̀ yí ìpínlẹ̀ Edo àti Delta, ó wá rọ àwọn ènìyàn láti máà tẹ̀síwájú láti máà tẹ̀lé àwọn ìlànà áàbò làti dènà àwọn àrùn tó ńràn, kí wọ́n dènà ẹ̀fọn kí wọ́n sì tún máà gbabẹ́rẹ́ àjẹsára lọ́dún mẹ́wa mẹ́wa.

Ọga àgbà ilé ìwòsàn UCH, tún kílọ̀ pé kí àwọn ọmọ ilẹ̀ yí máse túra sílẹ̀ pẹ̀lú bí àwọn orílẹ̀ èdè kan ti se tí ńkojú bí àrùn COVID-19 ti se ńgbérí fún ìgbà kejì.

Anthonia Akanji/Yẹmisi Dada

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *