News Yoruba

Àwọn tọ́rọkàn ti késíjọba láti wójùtú sọ́rọ̀ báwọn akọsẹ́mọsẹ́ lẹ́ka ètò ìlera se máà ń sá ròkè òkun.

Àwọn èekàn tọ́rọkàn ti láwọn ńfẹ́ kíjọba tètè wójùtú sọ́rọ̀ báwọn akọ́sẹ́mọsẹ́ lẹ́ka ètò ìlera se máà ń sáré lọ sókè òkun, láti dènà ewu tólè tìdí rẹ̀ súyọ.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pẹ̀lú ilé-isẹ́ wa Radio Nigeria, wọ́n tọ́kasi pé, ìgbésẹ̀ yíì se pàtàkì fún ilẹ̀ Nàijírìa, lọ́nà àti máà jẹ́kí ẹ̀ka ètò ìlera dẹnukọlẹ̀.

Wọ́n bẹnu àtẹ́lu ìgbésẹ̀ báwọn akọ́sẹ́mọsẹ́ lẹ́ka ètò ìlera se máà ń ròkè òkun labẹlẹ, láti máà wa ilẹ̀ ọlọ́ra káàkiri.

Onísègùn àgbà nílé ẹ̀kọ́sẹ́ ìsègùn òyìnbó ńlá UCH, ìbàdàn, ọ̀jọ̀gbọ́n Jesse Ọtẹgbayọ, tọ́kasi pé, ìgbésẹ́ náà le yọrísí àitó àwọn òsìsẹ́ elétò ìlera tí yóò máà mójútó báwọn èeyàn se pọ̀tó lórílẹ̀dè yíì.

Onímọ̀ kan nípa ìtọ́jú àisàn ọpọlọ, Dókítà Taiwo Okunade atonimọ kan, nípa ọ̀rọ̀ àyíka, ọ̀gbẹ́ni Ọlawale Ajani, dìjọ bèèrè fún ìpèsè àyíká tórọrùn àtàwọn ojúlówó irinsẹ́ fáwọn akọ́sẹ́mọsẹ́ elétò ìlera ọ̀hún, láti dènà wọn kúrò lẹ́nu ìrìnàjò míma sálọ sókè òkun.

Àwọn tọ́rọkàn náà, wá bèèrè fún ìlànà ètò ìlera tó poju owó nílẹ̀ Nàijírìa.

Akanji/Wojuade    

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *