Lẹ́nu ìgbésẹ̀ pé ó se e se kí kòkòrò àrùn covid-19 tún gbilẹ̀ bí ọ̀wàrà òjò fún ìgbàkejì lórílẹ̀dè yíì, ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá ilé-isẹ́ àarẹ lórí ọ̀rọ̀ covid-19, PTF, ti gbàwọn ọmọ ilẹ̀ Nàijírìa nímọ̀ràn láti yàgò kúrò nídi èyíkèyí ìrìnàjò tóníse ayẹyẹ ọdún kérésì àtọdún tuntun, lọ́nà àti mádinkù ewu kíkó àrùn corona.
Alága ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá ọ̀hún, ọ̀gbẹ́ni Boss Mustapha ló gbọ́rọ̀ àmọ̀ràn yíì kalẹ̀ níbi ìpàdé àwọn oníròyìn kan, pẹ̀lú àlàyé pé, wọ́n gbọ́dọ̀ tún sọ́ra se pẹ̀lú àpéjọpọ̀ ọlọ́pọ̀ èrò, nítorí pé, ewu ńbẹ lóko lóngẹ́ lórí ọ̀rọ̀ kíkó àrùn covid-19 lẹkan si.
Kò sài tọ́kasi pé, àwọn tó sẹ̀sẹ̀ ńlùgbàdì kòkòrò àrùn náà lè dàpọ̀ máwùjọlẹ́nu síseayẹyẹ ọdún kérésì yíì èyí tó sì se e se kó ran àwọn èèyàn min-in tí kò ní àrùn ọ̀hún rí nítorí dídúró sáwùjọ ibi térò bá pọ̀ si.
Sáajú lolùdarí ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá ilé-isẹ́ àrẹ, ọ̀gbẹ́ni Sani Aliyu, ti kéde pé, kò sí àni-àni lórí didewọ lórí àwọn òfin tó rọ̀mọ́ dídènà àrùn covid-19 sáajú àti lékokò ayẹyẹ, ọdún kérésìmesì.
Ọgbẹni Aliu sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, orílẹ̀dè Nàijírìa si ń kọminú lórí bí kòkòrò àrùn covid-19 se ń pelékesi yíká àgbáyé, ìdí sìnìyí tó fi sepàtàkì kíwọ́n fẹsẹ̀ òfin àtìlànà dídènà àrùn covid-19 múlẹ̀ daindain lákokò ìsinmi ayẹyẹ ọdún náà.
Aminat/Wojuade


