Wọ́n ti sàpèjúwe bọwọ àwọn ọ̀dọ́ se máà ń dilẹ̀, gẹ́gẹ́ ìsoro kan gbogi tó ń kojú ilẹ̀ Nàijírìa nítorí báwọn ìsèjọba tóréjọjá kò se pèsè àyíká tó rọrùn fáwọn ọ̀dọ́ láti jígìrì sí ojúse wọn.

Alákoso kejì fọ́rọ̀ ìpínlẹ̀ Niger Delta, Senator Ọmọtayọ Alasoadura ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yíì, nílu Àkúrẹ́ níbi ètò àpérò kan tó dá lórí àirísẹ́se àwọn ọ̀dọ́, ìfẹ́hónúhàn láti fòpin sí ikọ̀ Sars àtọ̀nà àbáyọ.

Senator Alasọaduratẹnumọ́ pé, àisí ìpèsè iná ọba tó dúró ree, ojú ti ko dára àtìwà ìbájẹ́ ti sàkóbá tíkò lẹgbẹ fún’lẹ̀ Nàijírìa fáimọye ọdún sẹ́yìn.

Sáájú, nínú ọ̀rọ̀ tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Òndó ọ̀gbẹ́ni Oluwarotimi Akeredolu ti kọminú lórí báwọn jàndùkú tó lo ànfàní ìfẹ̀húnúhàn fífòpin sí ikọ̀ Sars se ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkia ìjọba àti taládani jẹ́, wá sọpé, ìlànà ọ̀tun gbọdọ̀ jẹ́ gbígbẹ́ kalẹ̀ láti mú ìlọsíwájú bá ilẹ̀ Nàijírìa.

Gómìnà Akeredolu kò sài tẹnumọ ìdí tó fi sepàtàkì kíwọ́n se kóríyá fáwọn òsìsẹ́ ọlọ́pa ilẹ̀ Nàijírìa, láti mágbega bá dídàbò bo ẹ̀mí àti dúkia aráalu.

Ọlọrunferanmi Ọdófin/ Wojuade Fọlakẹmi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *