Yoruba

Àbá Òfin Kan Tóníse Pẹ̀lú Àtúnse Òfin Àjọ TETFUND Ọdún 2007, Ti Di Kíkà Fún Ìgbàkejì Nílé Asòfin Àgbà

Wọ́n ti ka àbá òfin kan tó níse pẹ̀lú síse àtúnse sí òfin àjọ tón fowo se agbátẹrù ètò ẹ̀kọ́ láwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga, tamọ̀sí Testfund tọdún 2007 fún igbákejì nílé ìgbìmọ́ asòfin àgbà.

Asòfin tón sojú ẹkùn ìdìbò àarin gbùngbùn Èkìtì, Sẹnatọ Micheal Ọpẹyẹmi Bamidele ló sagbátẹrù àbá òfin náà, tó si ń bèerè fún lílọ́wọ́ ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin bọnú àjọ Tetfund.

Lákokò tíwọ́n ń jíròrò lórí àbá òfin náà, Sẹnatọr Bamidele tọ́kasi pé, abala kẹrin, keje àti Ògùn òfin àjọ Testfund ló nílò àtúnse.

Gẹ́gẹ́ bó se sọ́ọ̀di mímọ̀, asòfin Bamidele ní látìgbà tíwọ́n ti sèdásílẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin, ló ti gbilẹ̀ bí ọ̀wàrà òjò káakiri tó sì tún kojú ọ̀kanòjọ̀kan ìpèníjà, ìdí sìnìyíì tó fi yọ, kílé ẹ̀kọ́ náà jànfàní látara ìgbáyégbádùn àjọ tó n towa se agbátẹrù ètò ẹ̀kọ́ àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga ọ̀hún.

Aminat Jibikẹ/Fọlakẹmi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *