Pẹ̀lú bí ìjọba àpapọ̀ seń fikun iye jálá epo àti àwọn èròjà tó rọ̀ mọ, ilé ìgbìmọ̀ asòfin ńfẹ́ kí wọ́n wá sọ bí wọ́n ti náà owó tó lé ní billiọnu mẹ́fàlélọ́gọ́ta naira tó wà nínú àbá ìsúná fún síse isẹ́ àkànse àtúnse àjọ tón mójútó epo rọ̀ọ̀bì NNPC, nínú àbá ìsúná ọdún 2021.

Alága ìgbìmọ̀ tón rísí ọ̀rọ̀ epo rọ̀ọbì nílé asòfin, Àlhájì Musa Sarkiadar ló gbé ìbére yi kalẹ̀ lásìkò tí wọ́n ńse àtúngbéyẹ̀wò àbá ìsúná ọdún 2020, àti sí sáláyé ọ̀nà tí wọ́n yo gbà ná owó tó wà nínú àbá ìsúná ọdún 2021 tó jẹ́ ti tàjọ ọ̀hún.

Ẹnìkan tó jẹ́ ọmọ ìgbòmọ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni Nicholas Ossai, tọ́kasi wípé, kò sí àkọọlẹ tó kún lórí bí àjọ NNPC, se náà owó láti tún ẹbu ìfọpo se nígbàtí àwọn asòfin yóòkù kọminú lórí bí àwọn olùdarí àjọ náà se se ìfilọ́lẹ̀ ẹbu ìfọpo nípinlẹ̀ Imo.

Olùdarí àgbà fájọ NNPC, ọ̀gbẹ́ni Mele Kyari sọ fún àwọn asòfin pé owó tí wọ́n yà sọ́tọ̀ nínú ètò ìsúná ọdún 2020 tójẹ́ àdọ́ta billiọnu naira, ni àdínkù ti débá nítorí ìtànkálẹ̀ àrùn coronavirus.

Ọgbẹni Kyari sọ pé, wọ́n ti ti ibùdó ìfọpo nítorí ó nira láti sisẹ́ bó se yẹ, ò wá fọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà fáwọn ìgbìmọ̀ asòfin pé àjọ náà ńsisẹ́ láti wójùtú sáwọn ẹbu ìfọpo.

Shehu/Idogbe Elizabeth

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *