Ọga àgbà yányán fún ilésẹ́ ọlọ́pa orílẹ̀èdè yíì, Ọ̀gbẹ́ni Muhammed Adamu ti rọ àwọn ọlọ́pa láti máse kárẹ ọkàn nídi isẹ́ tí wọ́n yàn láayo.

Ó sọ̀rọ̀ yíì lásìkò tó ńbá àwọn òsìsẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ Ògùn sọ̀rọ̀ lólú ilésẹ́ náà eléwéran nílu Abẹokuta lásìkò àbẹ̀wò rẹ̀ sáwọn ìpínlẹ̀ ìwọ̀-oorùn orílẹ̀èdè yíì.

Ọ̀gbẹ́ni Adamu sàlàyé pé, àbẹ̀wò náà wáyé láti se kóríyá fáwọn òsìsẹ́ ọlọ́pa, lẹ́yìn tí wọ́n pàdánù ọ̀pọ̀ ǹkan lákokò rògbòdìyàn Endsars.

Ó sàlàyé pé ìfẹ̀húnúhàn ọ̀hún kise láti fòpin sí ikọ̀ Sars nìkan, àmọ́ ìgbìyànjú láti dojú ètò ìsèjọba dee, kò sài wá gbóríyìn f’áwọn ọlọ́pa fún bí wọ́n tise fọmọnìyàn se nípa bíbu ọlá fún ẹ̀tọ́ àwọn aráalu.

Ọgbẹni Adamu ẹnitó pé fún ìgbésẹ̀ kíakía tako ìròyìn òofegè èyí tó ní pé òsokùnfà nigudu lákokò ìfẹ̀húnúhàn #EndSARS.

Sáajú alákoso fún ilésẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ Ògùn, Ọ̀gbẹ́ni Edward Ajogun sọpé àwọn òsìsẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ Ògùn ti padà sẹ́nu isẹ́ kówá wọn.

Wale Oluokun/Elizabeth Idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *