Rukerudo lo be sile lowuro oni ni ilu Tapa lagbegbe ibarapa nipinle Oyo, nitori pe ilo amotekun sekupa awon odo kan nirole ana.

Iroyin ni awon odo kan lagbegbe naa ni won ti ya sawon opopona, ti won si nba awon dukia je, tawon eniyan si ti bere sin ii sa asala femi won.

Awon meji ninu oloye agbege naa, Ogbeni Taiso Adeagbo ati Ogbeni Sunday Fadipe salaye wipe awon odo naa ni won ya sita nitori bi awon iko amorekun tise seku pa awon meji kan.

Akororoyin ile ise Radio Nigeria ri gbo wipe nise ni iko Amotekun fe dena ariya adugbo tawon odo kan fe se ni Tapa leyinti o yori si gbodo nroso to si sokunfa iku awon eeyan meji nigbati awon meje farapa.

Akitiyan lati gbo tenu alukoro ile ise olopa nipinle Oyo Ogbeni Olugbenga Fadeyi lori isele naa lo jasi pabo nitoripe ko gbe ero ibarenisoro re.

 Oluremi/Dada 

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *