Yoruba

Ilé isẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ fojú àwọn ọ̀daràn tótó méjìndíláàdọ́ta hàn fáyé

Àwọn tí wọ́n furasí bí ọ̀daràn tótó méjìdínláàdọ́ta tí wọ́n da ìlú ìbàdàn àti agbègbè rẹ̀ láàmu ni ilé isẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ ti fojú wọn hàn.

Àwọn tí wọ́n furasí bi ọ̀daràn wọ̀nyí lọwọ́ tẹ̀ lórí oníruru ẹ̀sùn bíì ìjìnigbé, ìfipábánilòpọ̀ ìdigunjalè àti àwọn ìwà ọ̀daràn miràn ọ̀kan lára wọn agbẹjẹ́rò ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gata Rẹmi Ọladiti ẹnití ọwọ́ tẹ̀ fún kíkun ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lóórun tó sì fipá báà lòpọ̀, tó wa ni ajọmọ oun àti ọmọ náà ni.

Ẹnití wọ́n funrasí miran, Jinbti Nimtim ẹnití ọwọ́ tẹ̀ fún ẹ̀sùn ìjínigbé àti pípa ọ̀gá rẹ̀ ló ní àwọn jí owó àti ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ olóògbe kí wọ́n tó táà fọ́rẹ wọn.

Lára àwọn tí wọ́n wọ́n tún fojú wọn hàn ni wọ́n jẹ́wọ́ pé lóòtọ làwọn jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n, tí wọ́n wá ńbèèrè fún áànu.

Nígbàtí wọ́n ńfojú wọn hàn, ọ̀gá àgbà fún ilé isẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, Arábìnrin Ngozi Onadeko sọ wípé isapa àwọn agbófinró ti so èso rere tó pọ̀.

Arábìnrin Onadẹkọ wá ní pẹ̀lú ìsapá àwọn òsìsẹ́ wọn àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ará ìlú yo àtìlẹyìn àwọn àjọ elétò áàbò yokù nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ silẹ, ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ yio bọ lọ́wọ́ ìwà ọ̀daràn.

Arábìnrin Ọnadẹkọ wá tọ́ka síì wípé lára àwọn tí wọ́n tún fojú wọn hàn láti ri àwọn tí wọ́n jí ẹrù àwọn àgọ́ ọlọ́pa gbé lásìkò ìfẹ̀húnúhàn láti fòpin sí ikọ̀ sars.

Makinde/Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *