Gómìnà alágbádá àkọ́kọ́ fún ìpínlẹ̀ Èkó, àlhájì Lateef Kayọde Jakande ti jáde láyé.

Alákoso fọ́rọ̀ isẹ́ òde tẹ́lẹ̀ ọ̀ún ló kú lówurọ̀ òní nílu Èkó léni ọfún mọ́kànléláàdọ́run.

Àlhájì Jakande ló jẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó láàrin ọjọ́ kini osù kẹwa ọdún 1979 àti ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n osù kejìlá ọdún 1983 lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú Unity Party of Nàijírìa, U.P.N ti olóòtu iwọ óòrùn ilẹ̀ yí tẹ́lẹ̀ olóyè Ọbafẹmi Awolọwọ dá sílẹ̀.

Ó jẹ́ oníròyìn kó tó di alákoso fọ́rọ̀ isẹ́ òde lábẹ́ ìsàkóse ọ̀gágun Sani Abacha láàrin ọdún 1993 sí 1998.

Nígbàtí ó ńsọ̀rọ̀ lórí ikú rẹ̀, Gómìnà Babajide Sanwo-Olu ti ìpínlẹ̀ Èkó sàpèjúwe àlhájì Jakande gẹ́gẹ́bí ọmọ ilẹ̀ yí tó dára tó sì sin ìpínlẹ̀ Èkó àti ilẹ̀ yíì dójú àmì.

Net/Dada   

 

 

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *