Lára akitiyan láti wójùtú sí áwọ̀ọ̀ tó wáyé lọ́jà sásá nílu ìbàdàn, Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, onímọ̀ẹ̀rọ Seyi Makinde, ti léwájú Gómìnà mẹ́rin ọ̀tọ̀tọ̀ láti áàpá ìlà-oorun ilẹ̀ yíì, lọsí àafin séríkí sásá, àlhájì Haruna meyaasin.

Àwọn Gómìnà ọ̀hún níì Abdullahi Ganduje tìpínlẹ̀ Kano, Bello Matawalle Zamfara, Abubakar Bajudu Kebi pati Abubakar Bello tìpínlẹ̀ Niger.

Lára àwọn èèyàn tó sèbẹ̀wò ohun tuni àwọn adarí lẹ́ka ètò àbò nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, olùbádámọ̀ràn pàtàkì sí Gómìnà Makinde fọ̀rọ̀ àbò, Fatai Owoseni, alága ìgbìmọ̀ olùgbanimọ̀ràn, sẹnatọr Hosea agboola àti sẹnatọr Mosurat Sumọnu.

Akọ̀ròyìn ilésẹ́ Radio Nàijírìa, jọ́bọ̀ pé okọ̀ alábo dúró wámú-wámú ní tìbú-tooro ọjà ọ̀hún.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, séríkí sásá nílu ìbàdàn, àlhájì Ahmọdu Zungeru, ẹnitó banújẹ́ púpọ̀ lórí ìsẹ̀lẹ̀ náà, gbóríyìn fún Gómìnà Makinde fún fífẹsẹ̀ àláfìa múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tójẹ́ hausa, láti ìgbà tóti gorí àléefà.

Nígbà tó wá ń sọ̀rọ̀, láàfin ọba náà, Gómìnà Makinde bèrè fún ìbásepọ̀ àláfìa, tósì sèlérí wípé ètò ìsèjoba òhun yóò wá gbogbo ọ̀nà láti dáà àláfìa padà lọ́tun.

Adebisi/idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *