News Yoruba

Àwọn Olùgbé Ìlú Ìbàdàn Kan Koroju Sí Ìgbésẹ̀ Báwọn Ilé-Isẹ́ Kan Se Ńgbépo Bẹtirolu Pamọ́

Pẹ̀lú bí ìjọba àtàwọn ẹgbẹ́ alágbàtà epo rọ̀bì níll yíì seti fọwọ́ sọ̀yà pé kò sóhun tó jọ ọ̀wọ́n gógó epo bẹtirolu yíká ilẹ̀ yíì, fibẹ gbogbo àwọn ilé epo tó wà nílu ìbàdàn nípinlẹ̀ ọ̀yọ̀, kò ti bẹ̀rẹ̀ isẹ́ tàarà.

Akọ̀ròyìn ilé-isẹ́ wa, tó tọpinpin bọ́rọ̀ tirí yíká àwọn agbègbè bi, Ring Road, Dùgbẹ̀, Òkè-Àdó àtagbègbè Alẹshinlọyẹ, jábọ̀ pé, kíì se ilẹkun wọn sílẹ̀ fáwọn oníbarà.

Oníròyìn ilé-isẹ́ Radio Nàijírìa kò sài tún wòye pé, ìtò àtòdábọ sí wa níwọ̀nba àwọn ilé-epo tó sí sílẹ̀, tíwọ́n ń ta èròjà ọ̀hún.

Méjì nínú àwọn awakọ̀ tó bóníròyìn ilé-isẹ́ Radio Nàijírìa sọ̀rọ̀, korò ojú sí ìgbésẹ̀ náà, tíwọ́n sọ pé, síse ló dàbí ìgbà téèyan fi ìyà jẹ aráalu láinidi.

Àwọn awakọ̀ náà, kò sài tún sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, ẹ̀ka tón rísọ́rọ̀ epo rọ̀bì nílẹ̀ yíì, DPR, kò ti dahun sí ìpè, ìgbétìpa àwọn ilé epo tó bá kọ̀ tíkò tajà fonibara.

A o ranti pé, ìlú ìbàdàn ló tún fojú winna ọ̀wọ́n gógó epo bẹtirolu láti òpin ọ̀sẹ̀ tókọjá, lórí ẹ̀sùn pé, àwọn ilé-epo kan ńko epo wọn pamọ́.

Akintunde/Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *