News Yoruba

Ilẹ̀ Nàijìrìa Ti Tẹ́wọ́ Gba Abala Àkọ́kọ́ Abẹ́rẹ́ Àjẹsára Tón Dènà Àrùn Covid-19

Bí ilẹ̀ Nàijírìa se ti ńtẹ́wọ́gba abala àkọ́kọ́ abẹ́rk àjẹsára tí yóò máà dènà àrùn covid-19 lágọ ara lóni, àwọn olùgbé ìlú ìbàdàn kan ti késí ìjọba àpapọ̀, láti sese dédé lórí ọ̀rọ̀ pínpín abẹ́rẹ́ àjẹsára ọ̀hún.

Ìlú ìbàdàn niwọ́n ti sọ̀rọ̀ yíì di mimọ̀ fákọ̀ròyìn ilé-isẹ́ wa, méjì lára àwọn olùgbé náà, ọ̀gbẹ́ni Owolabi Kareem àti ọ̀gbẹ́ni David Bello dìjọ sọpé, ó se pàtàkì fúnjọba láti yàgò fún ojúsajú síse lórí ọ̀rọ̀ abẹ́rẹ́ àjẹsára náà yíká orílẹ̀èdè yíì.

Àwọn olùgbé ọ̀hún kò sàtún rọ àwọn olórí nílẹ̀ yíì láti túbọ̀ sisẹ́ tọ bí wọ́n yóò serí abẹ́rẹ́ náà gbà lọ́pọ̀ si, èyí tí yóò to fún gbogbo ọmọ ilẹ̀ yíì.

Níbàyíná, àwọn asojú ìjọba àpapọ̀ ti tẹ́wọ́gba abẹ́rk àjẹsára tón dènà àrùn covid-19 ní pápákọ̀ òfurufú Nnamdi Azikwe tó wà nílu Abuja.

Banjọ/Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *