News Yoruba

Àjọ CAF Ti Wọ́gilé Ìdíje Ife ẹ̀yẹ Ilẹ̀ Adúláwọ̀ Tàwọn ọ̀jẹ̀ Wẹ́wẹ́ Fún Tọdún 2021

Àjọ CAF, tón ń se kòkárí eré bọ́ọ̀lu aláfẹsẹ̀ gbá nílẹ̀ adúláwọ̀ CAF, ti wọ́gilé ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ adúláwọ̀ tó jẹ́ tàwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ tọ́jọ́ orí wọn wà lábẹ́ ọdún metàdínlógún fún tọdún 2021.

Ìgbésẹ̀ náà ló wáyé nítórí ìtànkálẹ̀ àrùn covid-19, tófimọ́ àwọn ìpèníjà min-in tónbá àjọ náà fínra lẹ́ka eré bọ́ọ̀lu lágbayé.

Ìdíje náà tóyẹ kó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá sí ọjọ́ kọkànlé lọ́gbọ̀n osù kẹ́ta ọdún tawayíì, ni ìgbìmọ̀ tón rísí ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì lájọ CAF, tí wọ́gilé báyíì.

Fawọle/Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *