Yoruba

ìyàwò Gómìnà ọ̀yọ́, Tamunominini Makinde mọrírì àwọn obìnrin

Ètò ìpolongo ojú pópó láti fi sàmì àyájọ́ àwọn obìnrin lágbayé fún tọdún yi ni ìyàwò Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, arábìnrin Tamunominini Makinde se àgbékalẹ̀ rẹ̀.

Ètò náà ló ń wáyé pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ iléesẹ́ ọrọ àwọn obìnrin àtọ̀rọ̀ amúludun ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́.

Ètò ọ̀hún èyí tí àkórí rẹ̀ jẹ́ “Àwọn obìnrin nípò asíwájú níní ọjọ́ iwájú kan náà nínú ọ̀rọ̀ covid-19 lágbayé” èyí tí ó gbérasọ láti ilé ìjọba gba Òjé dé Agodi Gate.

Nígbà tó ń báwọn obìrin sọ̀rọ̀, alákoso fọ́rọ̀ àwọn obìnrin nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, arábìnrin Jọkẹ Sanni sàlàyé wí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀ àrùn covid-19 se àkọ́bá fún àwùjọ àgbáyé, àwọn obìnrin gbọ́dọ̀ borí ìpèníjà wọn.

Lára àwọn tó kópa níbi ètò ìwọ́de ìpolongo náà ni alákoso isẹ́ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, arábìnrin Funmilayọ Orisadeyi, àwọn akọ̀wé àgbà iléésẹ́ ìjọba àwọn obìnrin tó jẹ́ òsìsẹ́ ìjọba àti oníròyìn tí gbogbo wọn wọ asọ ẹgbẹ́jọdá fún ìsàmì àyájọ́ náà.

Àyájọ́ àwọn obìnrin lágbayé ló máà ń wáyé ní gbogbo ọjọ́ kẹjọ osù kẹta ọdọ́ọ̀dún.

Ọlarinde/Salaudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *